Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ laipẹ yii lo ti tu aṣiri ọna abayọ si awọn adojukọ to n koju orilẹ-ede yii.
Oloye Ọbasanjọ, Ẹbọra Owu lo sọrọ naa lana, Ọjọru, Wẹside nilu Owu, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lakooko to lọ ṣabẹwo si Ọba Adegboyega Dosunmu, Olowu tilu Owu fun ti ayẹyẹ ọdun Ọmọ Olowu, ti ọdun 2021.
Nibẹ ni Ọbasanjọ ti gba awọn ọmọ Naijiria lamọran lati fọwọsowọpọ, ki wọn si gba alaafia, ifẹ ati iṣọkan laaye, bi wọn ba n fẹ rere fun Naijiria lotitọ.
Ọbasanjọ, ẹni to tun jẹ Balogun tilu Owu sọ pe nipa ifọwọsowọpọ nikan, ki a si ṣiṣẹ papọ lo le mu ki Naijiria bori adojukọ.
No comments:
Post a Comment