Òmìnira Nàìjíríà! Wòlíì Ayọ̀délé tún ju bọ́mbù àsọtẹ́lẹ̀ ìbẹ̀rù síta, ó sọ àwọn adarí tí wọ́n máa jígbé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 29, 2021

Òmìnira Nàìjíríà! Wòlíì Ayọ̀délé tún ju bọ́mbù àsọtẹ́lẹ̀ ìbẹ̀rù síta, ó sọ àwọn adarí tí wọ́n máa jígbé


Bi ayẹyẹ ọdun mọkanlelọgọta ti orilẹ-ede Naijiria gba ominira ṣe n sunmọ etile, alaṣẹ, apaṣẹ ati oludari ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe ki awọn adari orilẹ-ede yii maa mura silẹ fun ijinigbe fun.
 
Wolii Ayọdele lo ju bọmbu asọtẹlẹ yii sita lakooko to n sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ ninu atẹjade to fi ranṣẹ si AWIKONKO lonii, Ọjọru, Wẹside, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan.
 
Agba ojiṣẹ Ọlọrun naa jẹ ko di mimọ pe lara awọn iran tuntun ti ọlọrun fi han oun laipẹ yii ni pe wọn yoo ji awọn agba adari Naijiria kan gbe, ati pe awọn kan ti n gbaradi lati kọlu Ariwa orilẹ-ede yii, to fi mọ ilu Abuja to jẹ olu-ilu Naijiria.
 
Ninu atẹjade naa ti Ọgbẹni Ọṣhọ Oluwatosin, ẹni to jẹ akọwe iroyin Wolii Ayọdele bu ọwọ lu lo tun ti sọ siwaju pe awọn agbebọn ti Taliban yoo dojukọ orilẹ-ede yii ki iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari too pari.
 
"Ayẹyẹ ọdun kọkanlelọgọta ti a gba ominira ko ni itumọ kankan, ko si idagbasoke, ijọba ti ṣe daadaa, ṣugbọn awọn to ku diẹ kaato fun ko gbadun rẹ. Ipaniyan rẹpẹtẹ, itajẹsilẹ, pupọ rẹ ṣi n bọ.
 
"Ohun ti Ọlọrun ba mi sọ wi pe ka maa reti lakooko igbominira ọdun yii ni pe aṣiri iwa ajẹbanu ninu ijọba yii yoo tu, ati pe awọn olori agbebọn bii ISIS, ISWAP ni wọn yoo mu balẹ.
 
"Awọn gomina kan yoo kabamọ wi pe awọn jẹ gomina nitori awọn iṣoro ti wọn yoo maa koju, paapaa lapa Ariwa orilẹ-ede yii. Ọpọ awọn ohun ikọkọ ni aṣiri wọn yoo tu, ti ifẹsunkan nla yoo si dide.
 
"Ẹ jẹ ka kun fun adura. Mo ri awọn agbebọn, ti wọn n ji awọn to wa nipo giga lorilẹ-ede yii gbe. Awọn agbegbe ti wọn ti wọn fẹẹ ṣọṣẹ lapa Ariwa ati Abuja ti wa nilẹ fun wọn. Ẹ jẹ ki ijọba gbadura lọjọ kin-in-ni, ọjọ keji ati ọjọ kẹta lati le tu Naijiria silẹ kuro ninu idunkooko, nitori pe awọn agbebọn tuntun yoo dide pẹlu awọn ohun ija igbalode to lagbara gidi.

"A ni lati gbadura lori ọrọ eto aabo wa, nitori pe awọn Taliban yoo dide gidigidi ninu ọdun tuntun yii, ti wọ yoo si ṣe ikọlu nla ki iṣakoso to wa nita yii yoo pari."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI