Ọrọ buruku toun tẹrin-in nigba ti baale ile ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Ọlaoluwa Jimọh n rababa bẹbẹ pe ki wọn daṣọ aṣiri boun, nitori pe iṣẹ eṣu pọnbele ni boun ṣe fun ọmọ bibi inu oun loyun.
AWIKONKO gbọ pe lati inu oṣu kẹfa ọdun yii ni Ọlaoluwa ti n ko ibasun fun ọmọ naa, ọmọ ọdun mọkandinlogun.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni o ti pẹ ti Ọlaoluwa ati iya ọmọ naa ti kọ ara wọn silẹ, to si jẹ pe obinrin naa lo n da tọju ọmọ rẹ.
Ọdun meji sẹyin ni wọn sọ pe Ọlaoluwa lọ fipa gba ọmọ naa lati wa maa gbe lọdọ oun, iyẹn nilu Ode-Rẹmọ, ipinlẹ Ogun.
Wọn ni oṣu kẹfa ọdun yii la gbọ pe Ọlaoluwa bẹrẹ sii ki ọmọ naa ti a fọrukọ bo laṣiri mọlẹ, to si n ko ibasun fun un karakara.
Gbogbo asiko naa ni wọn sọ pe Ọlaoluwa maa n dunkooko mọ ọmọ yii wi pe oun yoo pa a danu to ba fi le tu aṣiri naa sita fẹnikẹni, tani pe o lọ rin ni gberegbere ọna ti aṣiri le fi tu sita.
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni baba agbaaya naa sọ ọmọ rẹ di maṣiini Ibalopọ ninu ile ti wọn si ni iṣẹju iṣẹju ti kinni abẹ rẹ ba ti dide duro, lo maa n ko ibasun fọmọ naa lai roo lẹẹmeji.
Bi ọmọ ṣe loyun, lo ti gba ọdọ baba rẹ lọ lati ṣalaye, ṣugbọn ti wọn sọ pe baba naa tun ṣi n ko ibasun fun un karakara. Nigba to si rii pe baba yii ko fẹẹ jawọ ninu iwa adojutini naa, lo ba gbe ibẹru naa ti, to si gba teṣan ọlọpaa Ode-Rẹmọ lọ lati ṣalaye fun wọn nibẹ.
Ọjọ kẹrindilogun oṣu yii lọwọ pada tẹ Ọlaoluwa, to si ti jẹwọ pe lotitọ ni, ati pe iṣẹ eṣu ni, kii se ẹjọ oun.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe Ọlaoluwa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lẹkunrẹrẹ.
No comments:
Post a Comment