Ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii, Usman Alkali Baba ti ṣeleri eto aabo to peye fun ijọba ipinlẹ Kwara ati gbogbo awọn araalu patapata, to si ni asiko naa ti to fun gbogbo eeyan lati maa sun orun asundọkan nipa didiju mejeeji.
Nibi abẹ ti Baba ṣe lọ sipinlẹ naa lana, Ọjọru, Wẹside lo ti ṣeleri yii, to si ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe iranlọwọ to kun oju oṣuwọn lai ṣe ojusaaju.
Ṣaaju akoko yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ileeṣẹ eleto aabo yooku fun iranlọwọ eto aabo to peye.
No comments:
Post a Comment