Ó ṣẹlẹ̀ o! Lẹ́yìn àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọ̀délé, àwọn agbébọn bíi Taliban wọ Nàìjíríà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 27, 2021

Ó ṣẹlẹ̀ o! Lẹ́yìn àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọ̀délé, àwọn agbébọn bíi Taliban wọ Nàìjíríà


'Gbọ ohun ti Ẹmi Ọlọrun n sọ' lọrọ to wa nilẹ yii lati ṣiṣẹ lee lori.
 
Ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni Wolii Elijah Babatunde Ayọdele sọ asọtẹlẹ wi pe ki ijọba Naijiria mura gidigidi si ọrọ eto aabo orilẹ-ede yii, paapaa awọn ipinlẹ kọọkan nilẹ Hausa.
 
Kii ṣe pe Wolii Ayọdele deede ṣe ikilọ yii, iranṣẹ ati Wolii Ọlọrun naa sọ pe oun rii wi pe awọn agbebọn bii Taliban ti wọn gba ijọba orilẹ-ede Afghanistan ti n palẹmọ lati gbakoso awọn ipinlẹ kọọkan nilẹ Hausa.
 
Ninu ọrọ Wolii Ayọdele nigba naa, o sọ pe:
 
"Mo n ri awọn ẹgbẹ kan bi i Taliban ti wọn n dide nilẹ Afrika. Wọn n bọ lọna ara lati kọlu awọn orilẹ-ede kan nilẹ Afrika bii Burundi, Mali, Central Africa Republic, Benin Republic, Chad, Niger Republic, ati Naijiria.
 
"O maa lagbara gidi gan-an, nitori pe wọn ti n korajọ lati gbakoso awọn ipinlẹ kọọkan ni Naijiria bii Borno, Yobe, Adamawa, Nassarawa, Bauchi, Kaduna, Plateau, to fi mọ awọn agbegbe kan ni Benue ati Kogi.
 
"Mo ti kilọ tẹlẹ wi pe Boko Haram, ISWAP maa lọ, ṣugbọn awọn ẹgbẹ agbebọn miran maa dide, o ti n fẹẹ ṣẹlẹ bayii, ayafi bi ijọba ba tete dide lati koju ẹ. Ninu ija lati koju awọn agbebọn wọnyi, ẹ jẹ ki wọn wa oju Ọlọrun. fun itọni."
 
 
Lọsẹ to kọja yii ni iroyin tẹ wa lọwọ wi pe awọn ẹgbẹ agbebọn ẹlẹsin musulumi kan bii Taliban, ISWAP ṣọṣẹ buruku wọn nipinlẹ Borno, nibi ti wọn ti ba ina mọnamọna nla wọn jẹ, to si sọ gbogbo ilu sinu okunkun.

Bakan naa, ni ana, awọn agbebọn ISWAP tun ṣọṣẹ buruku wọn nipinlẹ Yobe, nibi ti wọn ti dẹ pakute iku silẹ fawọn ọmọ ogun ilẹ yii, ti wọn si tun pa awọn araalu rẹpẹtẹ ninu ikọlu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI