Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Rivers ti ju gbajugba Wolii-binrin nni, Edna Worleru ati Onyema Bright sẹwọn gbere lori ẹsun wi pe wọn pa ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Isreal Georgewill.
Wolii-binrin Edna Worleru, ni wọn loo da ṣọọṣi kan to wa lagbegbe Rumuche, ijọba ibilẹ Emohua, ipinlẹ Rivers silẹ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ṣe ni Edna fi majele pa Israel Georgewill.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Onyema Bright ati Israel toun naa jẹ Wolii ninu ṣọọṣi mi-in to wa lagbegbe Rumuche ni wọn jọ n yan ara wọn ni ale.
Wọn ni ki ifẹ ikọkọ awọn mejeeji ba a le tubọ pẹ ni Edna ṣe loun yoo ba Onyema ṣe oogun ifẹ, ko si fi sinu ounjẹ fun un. Wọn lo sọ pe bi Israel ba i fi le jẹ ẹ, yoo nifẹ rẹ titi lai ni, ayafi bi iku ba ya wọn.
Ọdun 2021 la gbọ pe gbogbo iṣẹlẹ yii waye. AWIKONKO gbọ pe bi Israel ṣe jẹ oogun ifẹ ti Onyema gbe fun un, lo ti ta teru nipa. Ko pẹ rara ti aṣiri fi tu sita wi pe Onyema lo wa nidi iku to pa Israel, ko to di pe wọn lọ gbe Edna to fun un ni majele to pe ni oogun ifẹ.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ l'Ọjọbọ, Tọside ana, Onidajọ Adolphus Enebeli sọ pe awọn ẹri toun ri gba fi han daju pe awọn mejeeji mọ-ọn-mọ pa Israel ni, ti wọn si gbọdọ jiya labẹ ofin.
No comments:
Post a Comment