Nítorí owó tí wọ́n jí kó sálọ nídìí 'ATM', sikiọ́rítì méjì ní bánkì dèrò ilé-ẹjọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 29, 2021

Nítorí owó tí wọ́n jí kó sálọ nídìí 'ATM', sikiọ́rítì méjì ní bánkì dèrò ilé-ẹjọ́


Lonii, Ọjọru, Wẹside lawọn baale ile meji kan, Friday Audu, ẹni ọdun mẹtalelogoji ati Haruna Anaja, ẹni ogoji ọdun foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun wi pe wọn ji owo banki ko salọ.

Idi ẹrọ ti wọn fi n gba owo, iyẹn ATM ti banki naa to wa lojule kẹtala, adugbo Joel Ogunnaike, Ikẹja, l'Ekoo la gbbọ pe awọn mejeeji ti ji owo to din diẹ ni miliọnu meji aabọ (N2.4m) naira.
 
AWIKONKO gbọ pe oṣiṣẹ banki to lọ ko owo sidi ATM fawọn onibara wọn lati ri owo gba lakooko ti ko ba si eeyan ni banki la gbọ o gbagbe lati tilẹkun.
 
Bi awọn eeyan ṣe lọ sile la gbọ pe awọn mejeeji sare lọ sibẹ, ti wọn si palẹmọ gbogbo owo to wa nibẹ salọ, iyẹn lọjọ karun-un, oṣu kẹjọ, ọdun yii.
 
Nigba tawọn mejeeji n kawọ pọyin rojọ niwaju Onidajọ D. S. Odukọya ti ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Ikẹja, awọn mejeeji sọ pe awọn ko jẹbi pẹlu alaye.
 
Onidajọ Odukọya faaye silẹ lati gba beeli awọn mejeeji pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, ẹni kọọkan pẹlu oniduro meji-meji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI