Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ ọkunrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Oluchi Okoye, ẹni ti wọn lo de onigbese rẹ mọlẹ ni ṣẹkẹṣẹkẹ bi ẹran Ileya l'Ekoo.
Iṣẹ awọn to n ya owo ele la gbọ pe Okoye n ṣe, ti wọn si ni bo ṣe n ya awọn eeyan lowo, lo tun n gba ele lori ẹ.
Ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin la gbọ pe Okoye ya Reuben Alozie lowo to din diẹ ni miliọnu marun-un (₦4.6m) naira, ti ko si tii ri owo naa gba tii dasiko yii.
Eti Reuben |
Gbogbo igbesẹ ti wọn sọ pe Okoye gbe lati le gba owo rẹ pada lọwọ Reuben lo ja si pabo, idi ree to fi pinnu lati lọ gbe e, to si de mọlẹ fun ọjọ kan gbako.
Lati ọjọ kejilelogun oṣu yii ti wọn sọ pe Okoye ti de Reuben mọlẹ bi ẹran iso, wọn nigba ti awọn ọlọpaa too debe lọjọ keji ni wọn to ṣẹṣẹ gba a silẹ.
Iyawo Reuben, Arabinrin Angela Reuben la gbọ pe o gba teṣan ọlọpaa Denton lọ lati fi to wọn leti wi pe ẹnikan ti ji ọkọ oun gbe, to si de mọlẹ bi ẹran Ileya to n reti ọjọ iku.
Wọn lawọn ọlọpaa ko fi ọrọ yii falẹ rara ti si sare lọ sibẹ lati lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ. Iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn ba Reuben nibi ti wọn de mọ sinu orun.
Okoye to de Reuben mọlẹ ree |
Loju ẹsẹ ni wọn ti sare tu silẹ, ti wọn si gbe Okoye, ti ọpọ awọn eeyan tun n pe ni PACA lọ teṣan wọn.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, CSP Adekunle Ajiṣebutu sọ pe lotitọ ni, ati pe ọga awọn, Hakeem Odumosu ti paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe iwadii Okoye daadaa, to si gbawọn araalu lamọran lati yee ṣe idajọ lọwọ ara wọn.
No comments:
Post a Comment