Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ọdaran nilu Yola, ipinlẹ Adamawa, ti ju gendekunrin ọmọ ọdun marundinlọgbọn kan, Bala Hassan sẹwọn ọdun meji gbako pẹlu iṣẹ aṣkara lori ẹsun wi pe o pe awọn ọlọpaa ni ole ati alọnilọwọgba.
Ojọ Iṣẹgun, Tuside ana ni ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Adamu Alhaji wọ Hassan lọ siwaju ile-ẹjọ naa ti Onọrebu Nuhu Garta lewaju fun.
Wọn ni ṣe ni Hassan sọ pe gbogbo awọn ọlọpaa ẹkun Jimeta ni ole ati alọnilọwọgba. Wọn ni Hassan sọ pe o tẹ oun lọrun lati ku danu, ju koun lọ darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa nitori pe ọdaran ni wọn.
Onidajọ Nuhu Musa Garta nigba to n gbe idajọ naa kalẹ paṣẹ pe ki Hassna lọ fi ẹwọn ọdun meji gbako gbara, tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo itanran.
No comments:
Post a Comment