Mílíọ̀nù kan ààbọ̀ láwọn ti Fúlàní darandaran ti sọ di aláì-nílé lórí ní Benue - Gómìnà Ortom tú àṣírí jáde - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 8, 2021

Mílíọ̀nù kan ààbọ̀ láwọn ti Fúlàní darandaran ti sọ di aláì-nílé lórí ní Benue - Gómìnà Ortom tú àṣírí jáde


Gomina Samuel Ortom tipinlẹ Benue ti sọ pe ko si nnkan to le pa oun lẹnu mọ lati ma sọrọ, paapaa nigba tawọn Fulani darandaran ti sọ awọn ti ko din ni miliọnu kan aabọ nipinlẹ naa sinu igbekun ayeraye.
 
Ortom sọ pe awọn eeyan naa lawọn Fulani darandaran ti sọ di alai-nile lori nitori ikọlu ojoojumọ wọn.
 
O ni pupọ awọn ilu to wa nipinlẹ naa lawọn Fulani ti ṣọṣẹ, nibi ti wọn ti ba ọpọlọpọ dukia jẹ, ti wọn si tun fẹmi awọn eeyan ṣofo danu, eyi to sọ pe ijọba apapọ orilẹ-ede yii ko ri nnkan ṣe si i.
 
Bẹ o ba gbagbe, lati b oṣu meloo kan ni aarin Gomina Samuel Ortom ati ijọba apapọ labẹ akoso Muhammadu Buhari ko ti gun rege nitori ikọlu awọn Fulani darandaran yii, to si n fojoojumọ tako ijọba Buhari wi pe ko gbe awọn igbesẹ to yẹ lori ọrọ eto aabo.
 
Bakan naa lo tun fẹsun kan ẹgbẹ Miyetti Allah Cattle Breeders’ wi pe awọn ni wọn n ṣagbatẹru oriṣiriṣi ipaniyan to n waye nipasẹ awọn Fulani darandaran.
 
Ortom sọrọ yii lakooko to n bawọn akọroyin sọrọ niluu Makurdi, ipinlẹ Benue, to si lawọn ọmọ ẹgbẹ Miyetti Allah naa ti leri wi pe awọn yoo tubọ maa kọlu awọn araalu wọn titi digba ti wọn yoo fi faaye silẹ lati maa fi maalu jẹko kaakiri ipinlẹ oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI