'Ara mee riri, mo ri ori ologbo latẹ' lorin to n jade lẹnu ọpọ awọn ara agbegbe Oke-Ijẹbu to wa nilu Akurẹ, ipinlẹ Ondo nirọlẹ ana, ọjọ Iṣẹgun, Tuside, nigba ti wọn sọ pe wọn deede ri oku ọmọbinrin arẹwa kan nitosi ṣọọṣi Ridiimu ati CAC to wa nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to le sọ pato bi oku ọmọbinrin naa ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yii tan ṣe debẹ, ṣugbọn sibẹ, ohun tọpọ awọn eeyan n sọ ni pe awọn afurasi ọmọ Yahoo ni wọn ṣiṣẹ buruku naa.
Aarin meji ṣọọṣi Ridiimu ati CAC Oke-Temidire to wa ni Oke-Ijẹbu la gbọ pe wọn ju oku ọmọbinrin arẹwa naa si, pẹlu aṣọ funfun ti wọn fi yii ka.
Lẹgbẹ oku naa la tun gbọ pe wọn gbe baagi ọlọra dudu (black nylon), eyi ti awọn nnkan bii nnkan bi ipara, oogun oyinbo, kainkan, pata ati beresia wa ninu ẹ si.
AWIKONKO gbọ pe ninu baagi naa ni wọn ti ri iwe pelebe kan ti wọn kọ ẹrọ ibanisọrọ to ni orukọ Joy ninu.
Lara awọn to ri oku yii ni wọn sare ranṣẹ sawọn ọlọpaa lati waa woran, ti wọn si lawọn ọlọpaa naa ni wọn pada gbe oku naa kuro lọ si mọṣuari, paapaa lati ṣayẹwo iru iku to pa a.
Nigba to n sọrọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Funmilayọ Ọdunlami sọ pe lotitọ ni iṣẹlẹ ọhun, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ awọn to ju oku naa sibẹ, ati iru iku to pa a.
No comments:
Post a Comment