Kwara: A kìí ná owó láì tẹ̀lé ìlànà - Ìjọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 25, 2021

Kwara: A kìí ná owó láì tẹ̀lé ìlànà - Ìjọba


Ìjọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn kii deede na owo lai jẹ pe wọn tẹle ilana ati ofin bi wọn ṣe n na owo, ati pe gbogbo owo ti wọn n na patapata lo wa ni akọsilẹ.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto iṣuna nipinlẹ naa, Arabinrin Oyeyẹmi Ọlasunmbọ Florence lo sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti, Furaide ana, nibi eto idanilẹkọọ kan ti wọn gbe kalẹ fun awọn alakoso ẹka ileeṣẹ ijọba, iyẹn Directors of Planning, Research and Statistics in Ministries, Departments and Agencies (MDAs) lojuna lati jẹ ki mọ ohun ti wọn n ṣe lẹka eto iṣuna.

O ni ko si iye owo ti ijoba ipinlẹ naa le fẹ na, o gbọdọ ti wa ninu akọsilẹ eto iṣuna, kii ṣe pe wọn yoo kan sare kọwọ bọ owo lati sọ pe awọn fẹẹ lo o.

Siwaju sii lo sọ pe bi ijọba ṣe n na owo, ati bi wọn ṣe n gbe eto iṣuna wọn kalẹ maa n lọ ni ibamu pẹlu agbekalẹ eto iṣuna apapọ, iyẹn National Chart of Accounts.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI