Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Kwara Political Front, KPF ti gbawọn eeyan lamọran lati jawọ kuro ninu oṣelu ẹtanu tawọn kan n ṣe lasiko yii, to si ni orukọ lo n bajẹ, nitori pe ko si ere gidi kan nibẹ.
Ko si nnkan meji to mu ki ẹgbẹ KPF sọrọ yii jade, bi ko ṣe ti ọrọ ti wọn sọ pe oludari ẹgbẹ Enetsud, Ọmọwe Alagbọnsi Abdullateef n sọ kaakiri, eyi to fi n da wahala silẹ kaakiri ipinlẹ naa.
Wọn ni ṣe ni Ọmọwe Alagbọnsi dide lati maa polongo ibo gomina fun ẹnikan to fẹẹ gbe jade lọdun 2023, eyi ti wọn sọ pe o n lo anfaani naa lati ba orukọ gomina wọn jẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ KPF, Adedeji Oyetunde gbe jade lo ti sọ pe awọn ohun ti ọkunrin naa n sọ kaakiri, kii ṣe otitọ, bi ko ṣe lati fi ṣi awọn eeyan lọkan lasan ni.
No comments:
Post a Comment