Kí Ọlọ́run tún fún Nàìjíríà ni irú Ààrẹ bí i ti Buhari ni ká máa gbàdúrà - Umahi bẹ àwọn aráàlú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 7, 2021

Kí Ọlọ́run tún fún Nàìjíríà ni irú Ààrẹ bí i ti Buhari ni ká máa gbàdúrà - Umahi bẹ àwọn aráàlú


Gomina ipinlẹ Ebonyi, David Umahi, ti sọ pe ki Ọlọrun fun orilẹ-ede Naijiria ni Aarẹ bi Aarẹ Muhammadu Buhari to nifẹẹ awọn araalu lọjọ iwaju.
 
Umahi sọ pe yoo dun mọ oun ninu bi aarẹ to n bọ lẹyin iṣakoso Muhammadu Buhari jẹ iru eeyan to ni ọkan rere bii ti ẹ.
 
Asiko ti Umahi n dahun ibeere awọn akọroyin lẹyin abẹwo to ṣe lọ sọdọ Aarẹ Buhari nile agbara orilẹ-ede yii, iyẹn Aso-Rock, Abuja lọjọ Aje, Mọnde, ana.
 
O ni gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu loriṣiriṣi ni wọn n ṣiṣẹ takuntakun lati gba tikẹẹti lati du ipo aarẹ orilẹ-ede yii, ati pe ki ipo naa bọ sọdọ wọn lọdun to n bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI