Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti tẹ awọn gendekunrin mẹta ti ẹ n wo yii, awọn ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju lati maa fi Kẹkẹ Maruwa lu awọn araalu ni jibiti lọ.
Ninu fọnran kan ti agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Abdullahi Haruna Kiyawa fi sita lomnii, Ojọru, Wẹside, lo ti jẹ ka mọ pe awọn ọlọpaa ẹkun Dala lo rọwọ to awọn mẹtẹẹta.
Kiyawa sọ pe aṣẹ ọga awọn, Sama’ila Shu’aibu Dikko lawọn ọlọpaa tẹle, ti wọn fi rọwọ to wọn.
Aminu Ayuba, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Ibrahim Yusuf, ọmọ ọdun mejidinlogun ati Sani Idriss Mohammad, toun jẹ ọmọ ogun ọdun lawọn mẹtẹẹta tọwọ tẹ naa.
Wọn ni ṣe ni wọn yoo gbe Kẹkẹ Maruwa ẹlẹsẹ mẹta naa sita, ti wọn yoo si maa wa ẹni ti wọn fẹ lu ni jibiti kaakiri.
Okan lara awọn ti wọn lu ni jibiti la gbọ pe o lọ fọrọ wọn to awọn ọlọpaa leti, ko to di pe wọn wa wọn lọ, ti ọwọ si pada tẹ wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa sọ pe awọn mẹtẹẹta yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment