Ìwà ọ̀daràn ni láti yá owó tí ìran tó n bọ̀ lẹ́yìn kò lè san tán - Ọbásanjọ́ pariwo síta fún ìjọba Buhari - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 21, 2021

Ìwà ọ̀daràn ni láti yá owó tí ìran tó n bọ̀ lẹ́yìn kò lè san tán - Ọbásanjọ́ pariwo síta fún ìjọba Buhari


Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe iwa ọdaran ni lati ya owo silẹ de awọn iran to n bọ lẹyin, paapaa owo ti agbara iran naa ko nii ka, ti wọn ko si ni le san tan.
 
Oloye Ọbasanjọ lo sọrọ yii nigba to n tako owo nla kan tijọba apapọ labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari fẹẹ lọ ya, to ni si gbese ti wọn fẹẹ jẹ yii yoo ṣe akoba nla fun iran to n bọ lẹyin lọjọ iwaju.
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Aarẹ Buhari kọ iwe si ile igbimọ aṣofin agba orilẹ-ede yii lati ya owo oni biliọnu mẹrin ($4,054,476,863) dọla ati miliọnu to le diẹ lẹẹdẹgbẹrin (€710) Euro.
 
Ninu lẹta naa ni Aarẹ Buhari ti sọ pe awọn nilo lati pari awọn akanṣe iṣẹ kan to n lọ lọwọ, ati pe owo to wa lapo ijọba apapọ orilẹ-ede yii ko ka a, idi to fi lawọn nilọ lati lọ ya owo naa. Bakan naa lo tun sọ pe awọn nilo owo kan ti wọn n pe ni Grant, eyi to jẹ miliọnu marunlelọgọfa ($125) dọla.
 
Bẹ o ba si gbagbe, ninu oṣu keje ọdun yii ni ile igbimọ aṣofin agba bu ọwọ lu owo oni biliọnu mẹjọ le die ($8.3b) ati ẹẹdẹgbẹta miliọnu din diẹ owo Euro, €490, eyi to ti wa lakọsilẹ laaarin ọdun 2018 si 2020.
 
Nigba to n sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan ti ileeṣẹ Channels, iyẹn nibi eto kan to waye lorilẹ-ede South Afrika, Oloye Obasanjọ sọ pebi wọn ba fi awọn gbese to ti wa nilẹ tẹle silẹ lai san an, yoo ṣe akoba pupọ fun ijọba to n bọ lẹyin.
 
Ọbasanjọ sọ pe ko si nnkan to buru ninu ki wọn lọ ya owo, ṣugbọn ohun ti wọn n fi owo yiya naa ṣe, ati ọna ti wọn fẹẹ gba san an pada sibi ti wọn ti ya a.
 
"Bi ẹ ba n ya owo, ti owo naa si n pọ si lojoojumọ fun iran to n bọ, ati eyi to tun n bọ lẹyin wọn, iwa ọdaran ni. Kin ni ẹ n ya owo fun?"

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI