Ìṣẹ̀ṣe Làgbà: Ẹ wo ọmọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún tó di adelé ọba l'Ékìtì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 29, 2021

Ìṣẹ̀ṣe Làgbà: Ẹ wo ọmọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún tó di adelé ọba l'Ékìtì


Lẹyin ipapoda Ọba Samuel Oyewọle Fadahunsi, Onijan tilu Ijan Ekiti to wa nijọba ibilẹ Gboyin, ipinlẹ Ekiti, awọn afọbajẹ ilu naa ti bu ọwọ lu Ọmọọbabinrin Adetutu gẹgẹ bi adele ọba.
 
Adetutu jẹ akọbi ọmọbinrin Ọba Fadahunsi to doloogbelaipẹ yii,

Ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan, ọdun 2002 ni Ọba Fadahunsi lati idile Otutubiosun gba ade gẹgẹ bi Onijan tilu Ijan Ekiti labẹ akoso Ọtunba Niyi Adebayọ, to si lo ọdun mọkandinlogun gbako lori itẹ.

AWIKONKO gbọ pe, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan, ọdun ti a wa yii ni Ọba naa jade laye, to si lọ ba awọn baba nla rẹ nibi ti wọn wa.

Nigba to n fi ontẹ lu Ọmọọbabinrin Adetutu gẹgẹ bi adele Ọba, alaga ijọba ibilẹ Gboyin, pẹlu ontẹ awọn agba oloye bii Oloye James Dada, Oloye Oluṣẹsan Fabamiṣe ati Oloye Kẹhinde Ojo, wọn jẹ ko di mimọ pe Adetutu lawọn fọwọ si.
 
Ninu lẹta naa ti wọn bu ọwọ lu lonii, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun 2021, ni wọn ti sọ pe bawọn ṣe bu ọwọ lu, ko ṣẹyin ti baba rẹ to wa lori ipo naa tẹlẹ, ẹni to ti papoda, ti ipo naa ko si gbọdọ ṣofo ṣaaju ọjọ ti wọn yoo yan ojulowo ọba miran.
 






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI