Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ohun gbogbo to ba nii ṣe pẹlu araalu, iyẹn awọn nnkan to le mu igbe aye irọrun ati alaafia ba awọn araalu lawọn yoo ṣe patapata, nitori pe ojuṣe awọn ni.
Laipẹ yii ni fọnran kan gun ori ayelujara, nibi ti wọn lawọn ara abule Dagbalodo to wa nijọba ibilẹ Patigi, ipinlẹ naa ti n wa ilẹ, ki wọn le ri omi mu.
A gbọ pe ko si omi mimu ninu abule naa, depodepo wi pe won yoo omi lo lati fi ṣe awọn nnkan to yẹ. Dipo bẹẹ inu ilẹ ni wọn ti lọ n wa omi ti wọn yoo lo.
Bi fọnran naa ṣe tẹ ijọba lọwọ ni wọn ti sọ pe anfaani lati tun tẹsiwaju lara awọn ojuṣe wọn ni fọnran ọhun jẹ, ati pe igbesẹ yoo bẹrẹ lati rii pe gbogbo awọn ara abule naa jẹ anfaani eto iṣejọba awaarawa.
Laipẹ yii ni ijọba yan awọn igbimọ ti yoo lọ ṣe iwadii lẹkunrẹrẹ nipa awọn agbegbe ti omi ẹrọ ko de, iyẹn lawọn ijọba ibilẹ bii Asa, Moro, patigi ti abule Dagbalodo wa, ati awọn miran.
Iwadii fi ye wa pe laaarin ọdun 2019 si 2021, ijọba ipinlẹ naa ti ṣe omi ẹrọ igbalode ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta sawọn agbegbe kaakiri ipinlẹ naa fun igbadun araalu.
Ni bayii, ijọba ti waa ṣeleri wi pe awọn yoo tun ṣi tẹsiwaju lati ṣe iwadii awọn agbegbe ti ko si omi fawọn araalu, ti wọn yoo si tete ṣee ko to pẹ ju.
Ninu ọrọ idaniloju ti kọmiṣanna to n sọrọ ipese omi, Alaaji Fẹmi Agaje sọ lo ti sọ pe awọn lọ ṣabẹwo si abule Dagbalodo lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee lati mọ ibi ti bata ti n ta awọn eeyan lẹsẹ, ki wọn si le ba wọn bu ororo itura sii.
No comments:
Post a Comment