Iléeṣẹ́ LEADERSHIP fún AbdulRazaq ní ààmì ẹ̀yẹ mánigbàgbé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 10, 2021

Iléeṣẹ́ LEADERSHIP fún AbdulRazaq ní ààmì ẹ̀yẹ mánigbàgbé


Ileeṣẹ iwe iroyin LEADERSHIP lo ti fun gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni aami ẹyẹ ti wọpọ gẹgẹ bi gomina to ṣe daadaa julọ lọdun to kọja, iyẹn ọdun 2020.
 
Ọjọbọ, Tọside ana ni ayẹyẹ naa waye, nibi ti gomina AbdulRazaq ti fi aami ẹyẹ naa sọri awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara fun atilẹyin wọn latigba to ti wa lori ipo ọhun.
 
Wọn ni kii ṣe pe wọn deede fun AbdulRazaq ni aami ẹyẹ yii, bi ko ṣe pe awọn ipa to ko lẹka eto ẹkọ, eto ilera, igbayegbadun araalu, ṣiṣe iranwọ fawọn to ku diẹ kaato fun ati awọn nnkan amayedẹrun fawọn araalu ni wọn wo, ti mu idagbasoke alailẹgbẹ ba ipinlẹ naa.
 

Gomina AbdulRazaq nigba to n sọrọ dupẹ gidigidi lọwọ ileeṣẹ iwe iroyin naa, to si ni awọn aṣeyọri oun ko ṣẹyin awọn ileri toun ti ṣe fawọn araalu, eyi to pọn dandan lati ṣe, ati pe ipinu oun ni lati jẹ ki ipinlẹ naa wa ni ipo iwaju laaarin awọn akẹgbẹ rẹ.
 
O loun dupẹ gidigidi lọwọ Ọlọrun to jẹ ki awọn ileri naa wa si imuṣẹ, to si loun fi aami ẹyẹ naa sọri Ọlọrun ati awọn ọmọ ipinlẹ Kwara.




Bakan naa, ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Ilorin Emirate Descendants Progressive Union, (IEDPU), ti gbe oṣuba kare fun ileeṣẹ LEADERSHIP lori bi wọn ko ṣe fi ọrọ ẹlẹyamẹya si bi wọn ṣe yan AbdulRazaq fun aami ẹyẹ yii.
 
Alaaji Aliyu Otta Uthman, to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa nigba to n sọrọ ninu atẹjade to fi ranṣẹ s'AWIKONKO sọ pe ẹni ti aami ẹyẹ naa tọ si ni wọn fun, ti ko si sọrọ ojusaaju nibẹ rara, nitori pe lati ọdun meji le diẹ sẹyin lo ti n dabira nipinlẹ Kwara.
 
O ni awọn idagbasoke ti AbdulRazaq ti mu wọn ipinlẹ naa ti jẹ ko kuro nipo ẹyin bọ si iwaju ni gbogbo ẹka loriṣiriṣi.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI