Gbajugbaja sọrọsọrọ nni, to tun maa n fi gbogbo igba gbe aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba larugẹ kaakiri agbaye, Ọmọọbabinrin Adejọkẹ Ṣomoye ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Ẹwa Ede ti pariwo sita fun ijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ orilẹ-ede Naijiria lati dide iranlọwọ fun aṣa ati iṣe, paapaa iṣẹ ọwọ ajogunba ilẹ Yoruba, ko ma ba a parun lojiji.
Nibi ipade ti Ṣomoye ṣe pẹlu awọn akọroyin niluu Abẹokuta, eyi to fi n bẹrẹ gbigbe aṣọ adirẹ larugẹ, nipa kikọ awọn ọdọ bi wọn ṣe n ṣee lo ti sọ eyi di mimọ.
Eto naa ti wọn pe ni ATTẸ 2021 ni ileeṣẹ rẹ GBAGEDE ẸWA EDE FOUNDATION ṣagbatẹru, to si fẹẹ fi ṣe iranlọwọ fun gbogbo ọdọ ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mẹjidinlogun si mejidinlogoji, paapaa awọn ti wọn ko niṣẹ lọwọ kaakiri agbaye, paapaa nipinlẹ Ogun.
Nigba to n sọrọ, Ṣomoye sọ pe:
"O jẹ ohun to banilọkanjẹ, to si maa n pa mi lẹkun wi pe ohun to jẹ ti wa ko jọ wa loju, paapaajulọ awọn ijọba wa. Ọna ti mo fẹẹ gba lati jẹ ki ijọba karamasiki ọrọ aṣa ati iṣe ilẹ wa, paapaa awọn iṣẹ ajogunba wa bi aṣọ Adirẹ ni pe mo fẹ ki ẹyin akọroyin mọ pe ohun ti ẹ ba sọ fun ijọba ni ijọba maa gbọ.
"Mo fẹẹ mọ boya ijọba maa laju silẹ lati jẹ ki awọn nnkan aṣa ajogunba wa parun, ati pe ṣe nitori kii ṣe pe wọn ko gbe 'ogun' ati 'ṣango' silẹ fun wọn lati fi bura ti wọn ba fẹẹ wọle, ṣe idi ree ti wọn fi fẹẹ laju silẹ ki aṣa ati iṣe Yoruba parẹ?
"Nitori idi ti a fi wa nibi lonii, ọpọlọpọ awọn ti wọn wa nibi idi aṣọ Adirẹ ṣiṣe ti aṣọ ti awọn orilẹ-ede China tun n ko wa fun wa. Awọn eeyan kan wa nidi Aro yii to jẹ pe wọn ko ni owo lati fi ṣe okoowo yii, iṣẹ ti wọn n ṣe nibẹ ni pe ti ẹni to ni owo lati fi ra aṣọ ati aro ba ti ṣe aṣọ tan, ohun kan maa ko o lati lọ ṣan an, owo to ba gba nibẹ lo fẹẹ fi fun ọmọ rẹ lounjẹ.
"Iṣẹ ti ẹlomiran n ṣe nibẹ ni lati lọ lu awọn aṣọ yii, owo to ba gba nibẹ lo fẹẹ fi fun ọmọ rẹ lounjẹ. Iṣẹ ẹlomi-in ni lati ba wọn ka aṣọ kuro nibi ti wọn saa si wọle, owo aṣọ to lọ ka yẹn lo fi n fun ọmọ rẹ lounjẹ. Ṣe ijọba maa wa laju silẹ, ki ounjẹ bọ lẹnu gbogbo awọn wọnyii?
"Nitori pe funra wọn ni wọn ronu iṣẹ yii, kii ṣe ijọba lo pese rẹ fun wọn. Awọn to wa iṣẹ funra wọn yii, ki ijọba ma ṣe laju silẹ jẹ ki iṣẹ naa tun bọ mọ wọn lọwọ, nitori ọpọlọpọ awọn ọdọ to wa nile-ẹkọ lo jẹ pe iṣẹ yii ni awọn obi wọn fi n ran wọn lọ.
"Awọn aṣọ adirẹ to n wọle lati ilẹ China yii, wọn ti pari iṣẹ lori ẹ, ti ko fi si wahala ati idaamu kankan, ko si si iṣẹ ti awọn to wa nidi Aro tun fẹẹ ṣe mọ. Fun idi eyi ni mo fi fẹ ki ijọba mọ pe awọn daran ti iṣẹ kekeeke yẹn ba tun bọ lọwọ awọn mẹkunnu.
"Idi ti awọn aṣọ naa si fi n raaye wọle ni pe gbogbo awọn eroja ti a fi n ṣe aṣọ Adirẹ ti n gbe owo lori gọbọi. Nigba ti aṣọ Adirẹ wa ba si ti gbe owo lori ju, yoo fun awọn atilaawi yii lanfaani lati ta aṣọ ti wọn lowo pọọku, idi ree tawọn eeyan fi n sare lọ raa.
"Mo wa fẹ ki ẹyn oniroyin ba mi sọ fun ijọba wi pe wọn ti rugi oyin bi ounjẹ ba tun bọ lẹnu mẹkunnu nipa jijẹ ki iṣẹ ọwọ ajogunba wa parun."
Lara awọn alejo pataki to wa nibi ipade awọn oniroyin naa ni Baṣọrun Ọladipupọ Adegbite, Amofin Habeeb Whyte.
No comments:
Post a Comment