Èyí làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọ̀délé tó tún ti wá sí ìmúṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 20, 2021

Èyí làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọ̀délé tó tún ti wá sí ìmúṣẹ


Lati bi ọsẹ bii meji si mẹta sẹyìn ni awọn eeyan tun ti bẹrẹ sii gbe oṣuba kare fun Ọba to da ọrun ati aye, pẹlu bo ṣe fi iṣẹ iranṣẹ tootọ ran aláṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical to wa nilu Eko, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele.

Bo tilẹ jẹ pe ko lonka awọn asọtẹlẹ Wolii Ayọdele fun ọdun 2021 ti a wa yii lo ti wa si imuṣẹ, ti awọn eeyan si jẹri sii pe lotitọ ni.

Ṣugbọn sibẹ, laipẹ yii ni awọn asọtẹlẹ miran tun wa si imuṣẹ, lara wọn si ni ti ọgba ẹwọn ti wọn ja danu, eyi to mu ki awọn ẹlẹwọn na papa bora.

Ninu iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun ti Wolii naa maa n gbe jade lati fi sọ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ, iyẹn Warnings To The Nations, ti ọdun 2021 lo ti mẹnuba a wi pe wọn yoo ja ọgba ẹwọn, ti awọn ẹlẹwọn yoo si salọ.

Ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin la gbọ pe awọn agbebọn yabo ọgba ẹwọn kan nipinlẹ Kogi, nibi ti wọn ti tu awọn ẹlẹwọn ti ko din ni igba ati ogoji (240) silẹ.

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe awọn agbebọn kan ti lọ tu awọn ẹlẹwọn silẹ nipinlẹ Ẹdo, to si jẹ pe Wolii Ayọdele ti sọ ọ di mímọ̀, to si wa ni akọsilẹ pe nnkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ.

Ninu ọrọ Wolii Ayọdele lo ti gba ijọba orilẹ-ede Naijiria lamọran wi pe ki wọn mura giri, ki won si rii daju pe wọn mura sọrọ eto aabo awọn ọgba ẹwọn kaakiri.

Àsọtẹlẹ yii wa ni oju ewe kọkandinlọọrun (299) iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun, Warnings To The Nations fun ti ọdun 2020/2021.

Siwaju sii, ni Wolii Ayọdele tun sọ pe eto ọrọ aje Naijiria yoo dẹnu kọlẹ, to si jẹ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ lakooko yii ti n fihan pe asọtẹlẹ naa ti n wa si imuṣẹ.

Owo dọla lasiko taa pari akojọpọ iroyin ti lọ soke kọja sisọ si owo ilẹ wa, iyẹn naira, bẹẹ si ni gbogbo ohun tawọn eeyan n fi owo ra n gbe owo lori lojoojumọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI