Ẹ̀wọn gbére n rùn lórí R. Kelly, gbajúmọ̀ olórin àgbáyé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 28, 2021

Ẹ̀wọn gbére n rùn lórí R. Kelly, gbajúmọ̀ olórin àgbáyé


Bi iwadii ṣe ti fidi rẹ mulẹ bayii wi pe gbajugbaja olori agbaye nni, R. Kelly jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an, wọn ti ni o ṣee ṣe lo fi ẹwọn ọdun mẹwaa gbako gbara, tabi ko pe ko lọ lo eyi to ku nigbesi aye rẹ lọgba ẹwọn.
 
R. Kelly to kọ gbajumọ orin “I Believe I Can Fly” nni, la gbọ pe o jẹbi ẹsun ko maa bawọn obinrin, awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin kekeeke laṣepọ.
 
Ẹsun mẹsan an ọtọọtọ ti wọn fi kan R. Kelly, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, la gbọ pe o jẹbi rẹ patapata. 
 
Nigba to n sọrọ lori awọn ẹsun naa, igbakeji adajọ agba ilẹ Amẹrika, Maria Cruz Melendez sọ pe ọrọ to wa nilẹ yii kii ṣe ti gbajumọ olorin, bi ko ṣe ti ọlọdẹ eeyan {predator}.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI