Ètò ààbò fẹ́ẹ́ gbọ̀nà àrà yọ ní Kwara, ilé-iṣẹ́ ológun ṣèlérí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 27, 2021

Ètò ààbò fẹ́ẹ́ gbọ̀nà àrà yọ ní Kwara, ilé-iṣẹ́ ológun ṣèlérí ìfọwọ́sowọ́pọ̀


Lojuna lati jẹ ki eto aabo ipinlẹ Kwara gun oke agba sii, ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe awọn ti tọwọ bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ ologun orilẹ-ede Naijiria, fun aabo ẹmi ati dukia awọn araalu.
 
Ijọba Kwara lawọn fẹ ki ileeṣẹ ologun orilẹ-ede yii ba wọn daabo bo gbogbo awọn ẹnubode to wọ ipinlẹ naa, eyi ti yoo jẹ kawọn araalu sun orun asundọkan pẹlu oju mejeeji.
 
Wọn ni gbogbo awọn agbebọn, ati agbanipa, to fi mọ awọn ajinigbe ti wọn ba fẹẹ gba awọn ẹnubode, paapaa ẹnubode Vobera to wa nijọba ibilẹ Kaiama wole sipinlẹ naa lawọn fẹ ki ileeṣẹ ologun ti 22 Armoured Brigage ti baraaki Sobi bawọn koju, ki wọn si le kapa wọn.
 
Nigba to n fọkan Gomina AbdulRahman AbdulRazaq balẹ, ọga agba ileeṣẹ ologun naa, Brig Gen Abdulsalam Abubakar ti sọ pe ko sewu lẹgbẹrun ẹkọ, awọn yoo daabo bo ipinlẹ naa kuro lọwọ awọ ọdaran to ba fẹẹ wọle wa, paapaa lati ipinlẹ Niger.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI