Ẹ fọkàn balẹ̀, ìṣòro omi mímu máa tóó dìrọ̀rùn láìpẹ́ - Ìjọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 25, 2021

Ẹ fọkàn balẹ̀, ìṣòro omi mímu máa tóó dìrọ̀rùn láìpẹ́ - Ìjọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lati ni suuru fun omi ẹrọ igbalode to daṣẹ silẹ lojiji.

Wọn ni nnkan to fa airi omi lo lasiko yii, ko ṣẹyin bi awọn irinṣẹ to n gbe omi jade lati odo Asa ṣe daṣẹ duro lojiji, ṣugbọn ti wọn sọ pe igbesẹ ti n lọ lati tun un ṣe.

Ninu atẹjade ti Alaaji Wahab Fẹmi Agbaje, ẹni to jẹ kọmiṣanna f'ọrọ ipese omi nipinlẹ naa fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe gbogbo awọn agbegbe ti omi naa ko de nilu Ilọrin lawọn ti n ṣiṣẹ le lori.

Alaaji Agbaje sọ pe ọpa to n gbe omi jade lọ sinu agba omi nla nilu Ilọrin lo daṣẹ silẹ lojiji, to si sọ pe ko si ohun meji to fa a, bi ko ṣe yi igi nla kan to wo luu mọlẹ.

O ni ojo to rọ laipẹ yii lo fa ijamba naa, to si ni ki gbogbo awọn araalu lọ fọkan balẹ nitori pe laipẹ, igbadun omi yoo tun bẹrẹ lakọtun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI