Bí o ṣe lè wo 'The Return of the King Of Boys' táwọn ayé n pariwo rẹ̀ lásìkò yìí rèé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 1, 2021

Bí o ṣe lè wo 'The Return of the King Of Boys' táwọn ayé n pariwo rẹ̀ lásìkò yìí rèé


Ayafi bi a ba fẹẹ tan ara wa jẹ, ko si fiimu meji tawọn eeyan n pariwo rẹ lasiko yii, to kọja Ipadabọ Oba Awọn Tọọgi, iyẹn The Return of the King of Boys, eyi ti Kẹmi Adetiba gbe jade.
 
Latigba tawọn eeyan ti wo apa kin-in-ni fiimu agbelewo naa, ti wọn si rii pe ko tii pari, ni wọn ti n bẹbẹ pe ki Kẹmi Adetiba tete gbe apa keji to ku jade, kawọn le jẹ igbadun rẹ.
 
Pupọ awọn ti wọn ti ro pe apa keji ni Kẹmi Adetiba yoo gbe jade, ti yoo si pari gbogbo fiimu naa lo ya lẹnu nigba ti wọn gbọ pe ipele meje ọtọọtọ ni fiimu naa jade, iyẹn Seven Episodes.
 

Ojọ Eti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, iyẹn, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ to ṣẹṣẹ pari yii ni fiimu naa jade si ori ikanni ileeṣẹ Netflix to maa n gbe awọn akanṣe fiimu agbaye jade.
 
Lara awọn to kopa ninu fiimu yii ni Ṣọla Ṣobọwale (Ẹniọla Salami), Toni Tones (Ẹniọla Salami), Nse Ikpe-Etim (Jumọkẹ Randle), Richard Mofẹ-Damijo (Reverend Ifeanyi), IllBliss (Odogwu Malay), Deyẹmi Ọkanlawọn (Adetọla Faṣhina), Efa Iwara (Dapọ Banjọ), Char (President Mumusa).
 

Ipele meje ti fiimu ọhun si ni:

1. A King's Welcome 60m
Watch A King's Welcome. Episode 1 of Season 1.
 
2. A Wounded Lion Is Still A Lion
Watch A Wounded Lion Is Still A Lion. Episode 2 of Season 1.
 
3. An Old Enemy
Watch An Old Enemy. Episode 3 of Season 1.
 
4. The Devil's Revenge
Watch The Devil's Revenge. Episode 4 of Season 1.

5. Walls Closing In

Watch Walls Closing In. Episode 5 of Season 1.

6. Trouble Sleep...

Watch Trouble Sleep.... Episode 6 of Season 1.

7. A Handover Ritual
Watch A Handover Ritual. Episode 7 of Season 1.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI