Balógun, ọmọ ìpínlẹ̀ Òndó tó fẹ́ràn láti máa já fóònù gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn ti há o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 1, 2021

Balógun, ọmọ ìpínlẹ̀ Òndó tó fẹ́ràn láti máa já fóònù gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn ti há o


"Ẹ foju aanu wo mi, iṣẹ eṣu ni", lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n jade lẹnu baale ile, ẹni ọdun mẹrindinlogoji kan, Olajide Balogun, ẹni ti wọn lo fẹran lati maa ja foonu gba lọwọ eeyan kaakiri igboro ilu Eko.

Owọ ileeṣẹ ọlọpaa Rapid Respond Squad, RRS nipinlẹ Eko lo tẹ Balogun laipẹ yii lagbegbe Shasha si Alimọṣọ, nipinlẹ naa.

AWIKONKO gbọ pe Balogun ko niṣẹ meji to n ṣe jẹun, to kọja wi pe ko ja foonu gba, ko si lọ ta a danu lowo pọọku. Wọn ni bi Balogun ba ti ja foonu gba, ṣe ni yoo fi ilu Eko silẹ salọ silu miran lati lọ farapamọ, bi wahala naa ba si ti lọ silẹ, ṣe ni yoo tun pada wa.

Ori ọkada la gbọ pe o wa tọwọ fi tẹ ọmọ bibi ilu Akoko, nipinlẹ Ondo naa. Wọn ni bo ṣe ri awọn ọlọpaa, lo sare bọ silẹ lori ọkada naa, to si juba ehoro, ṣugbọn ti wọn pada lee mu.

Adekunle Ajiṣebutu to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko nigba to n fidi iroyin naa mulẹ sọ pe Balogun ti jẹwọ wi pe ẹnikan to n jẹ Emeka loun maa n ta awọn foonu naa fun ni Computer Village to wa ni Ikẹja, l'Ekoo.

O wa ni ọga awọn, Hakeem Odumosu ti paṣẹ pe ki wọn wa Emeka naa lọ, ki wọn si foju gbogbo awọn to ba lọwọ si iwa buruku yii ba ile-ẹjọ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI