Ayé ò! Wọ́n ní ará Òkèlè, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà kò yá gidi o, ádùrá ló kù tàwọn èèyàn n gbà fun un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 7, 2021

Ayé ò! Wọ́n ní ará Òkèlè, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà kò yá gidi o, ádùrá ló kù tàwọn èèyàn n gbà fun un


Iroyin to tẹ wa lọwọ ti fi ye wa pe ara gbajugbaja oṣere tiata adẹrinpoṣonu nni, Babatunde Usman, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Okele ko ya gidi, to si nilo adura awọn eeyan.
 
Aisan kan ti a ko tii le fidi rẹ mulẹ la gbọ pe o kọlu Okele lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin, ṣugbọn to n gba itọju.
 
Lẹnu ọjọ meloo kan sẹyin la gbọ pe aisan naa gbọna miran yọ, to si mu ki ọkan awọn to sunmọ ma balẹ mọ.

AWIKONKO gbọ pe ipo ti Okele wa lakooko yii, iranlọwọ owo gidi lo nilo, lati fi gba itọju to pe ye, ko si le pada soko ere ori itage rẹ to yan laayo. 
 
Ọkan lara awọn oṣere tiata to ṣabẹwo si Okele, nibi to ti ya fọnran oniṣeju perete kan, eyi to fi n jẹ ki gbogbo aye mọ pe loootọ lara rẹ ko ya gidi, to si nilo iranlọwọ owo.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI