Ṣẹnkẹn bayii ni inu awọn oṣiṣẹ ijọba patapata nipinlẹ Kwara n dun, pẹlu bi Gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe fun gbogbo wọn ni lẹta igbega lẹnu iṣẹ.
Pupọ awọn ti wọn ti tọ si igbega, iyẹn awọn to ṣe idanwo igbega laipẹ yii la gbọ pe gomina bu ọwọ lu igbega wọn, to si tun fi lẹta ontẹ tii nidii fun gbogbo wọn.
Ida-mejidinlọgọrun le ni mẹtadinlaadọrun (98.87 percent) la gbọ pe wọn yege ninu awọn to ṣe idanwo igbega naa, ti wọn si ti gba iwe igbega wọn.
Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Kwara (Kwara State Civil Service Commission), Hajia Habeebat Anikẹ Yusuf lo sọ eyi di mimọ lori redio Sobi to wa niluu Ilọrin, iyẹn lori eto ti wọn pe ni IJOBA AWARAWA.
Yusuf sọ pe gbogbo awọn to tọ si igbega lọdun 2020 to kọja ni wọn ti gba lẹta igbega wọn, ti ipalẹmọ igbega tọdun 2021 naa si ti bẹrẹ ni pẹrẹu.
Nibẹ ni Yusuf ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori bo ṣe fun awọn oṣiṣẹ ni lẹta igbega wọn, pẹlu awọn ẹtọ to tọ si wọn patapata.
No comments:
Post a Comment