Gomina Abdullahi Umar Ganduje tipinlẹ Kano ti jẹ ko di mimọ pe ipinlẹ naa ti ṣetan fun ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), eyi to fẹẹ waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii.
Ọjọ Iṣẹgun, Tuside ana, ni Gomina Ganduje sọrọ naa sita nibi ipade awọn aṣiwaju, iyẹn State Executive Congress, to waye nile ijọba, nilu Kano.
"Ipade gbogboogbo ti wọọdu waye. Ti ipade gbogboogbo tijọba ibilẹ naa si tẹlee. Lẹyin ti wọn bura fun awọn alaga ẹgbẹ ni wọọdu, a n duro de ki wọn bura fun awọn alakoso tijọba ibilẹ ti wọn dibo yan lọsẹ meloo kan sẹyin.
"A ti n gbaradi fun ipade gbogboogbo tipinlẹ. A ti n ṣe gbogbo ohun to yẹ, fun ipalẹmọ ipade gbogboogbo tipinlẹ."
Siwaju sii, ni Gomina Ganduje sọ fun gbogbo awọn kọmiṣanna, awọn oludamọran patapata lati yọju sibi ayẹyẹ ominira ti yoo waye lọjọ Ẹti, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, to si jẹ ko di mimọ pe Malamu Muhammad Garba to jẹ kọmiṣanna fọrọ iroyin ni yoo lewaju igbimọ lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment