Aṣewo ni Lanre Tẹriba n fowo gbe kaakiri, ko le da tọju ọmọ rẹ mọ - Iya ọmọ rẹ pariwo sita faraye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 21, 2021

Aṣewo ni Lanre Tẹriba n fowo gbe kaakiri, ko le da tọju ọmọ rẹ mọ - Iya ọmọ rẹ pariwo sita faraye


Ọkan lara awọn obinrin to bimọ fun gbajugbaja onkọrin igbagbọ nni, Lanre Tẹriba, Arabinrin Diamond Gold lo ti gba ori ikanni ayelujara ti Insitagiraamu rẹ lọ bayii lati yẹyẹ ọkunrin naa, to si ni ẹni ti ko bikita fun ọjọ iwaju ọmọ rẹ ni.
 
Diamond Gold sọ pe dipo ki Lanre Tẹriba ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Atoriṣe tọju ọmọ to bi, ko si fun un ni ẹkọ gidi, awọn alaṣẹwo ati mọto lo n fi owo gbe kaakiri.
 
O ni ẹtanjẹ ni Lanre Tẹriba fi foun loyun nigba tawọn pade, lai mọ pe kii ṣe ẹni teeyan le maa pe ni ọkọ tabi ololufẹ. O ni ṣe lo sọ foun pe oun pẹlu iyawo oun ti ja, ati pe awọn ko si papọ mọ, eyi to jẹ koun gba fun un nigba naa.
 
Latigba to sọ pe oun ti loyun, lo ni Lanre Tẹriba ti pa oun ti, ti ko si ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bi baba ọmọ toun bi fun un.

Siwaju sii, lo tun fi awọn ẹri boun pẹlu onkọrin naa ṣe jọ sọrọ, to si loun ko le tọju ọmọ rẹ, to si jẹ pe obinrin, paapaa awọn alaṣẹwo lo n fowo ko kaakiri.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI