Àríyá Rẹpẹtẹ: Túnjí Buhari, ọmọ ẹ̀yìn Saraki tẹ́lẹ̀rí darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 29, 2021

Àríyá Rẹpẹtẹ: Túnjí Buhari, ọmọ ẹ̀yìn Saraki tẹ́lẹ̀rí darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC


Ẹsẹ ko gbero lonii nilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara nigba ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹyin Sẹnetọ Bukọla Saraki to jẹ aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorilẹ-ede yii tẹlẹri, Malaamu Tunji Buhari darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Tunji Buhari, ti iroyin fi to wa leti lọsẹ to kọja yii wi pe o ti n gbero lati darapọ mọ APC ni wọn ṣe ayẹyẹ nla fun lati gba a wọle sinu ẹgbẹ naa.
 
Oṣu bii meloo sẹyin la gbọ pe Buhari fẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, to wa tẹlẹ silẹ, ti ko si ṣẹgbẹ kankan.

Inu ọja Awodi, to wa lagbegbe Gambari, ilu Ilọrin ni ayẹyẹ naa ti waye nirọlẹ oni, Ọjọru, Wẹside.
 
Bayii ni eto naa ṣe lọ si lori ikanni fesibuuku:

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI