Ọọni Ile-Ifẹ, Alayeluwa, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti sọ pe ki gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lọ fi ọkan wọn balẹ patapata, nitori pe gbogbo adura tawọn ṣe fun orilẹ-ede yii nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ ni yoo mu idagbasoke ati ilọsiwaju rere ba Naijiria.
Alayeluwa Ogunwusi, Ọjaja keji lo sọ eyi di mimọ lọjọ Aje, Mọnde ana, nilu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun, lakooko to lọ ṣabẹwo si agboole to ti jade wa, eyi to wa ninu eto ati ilana ọdun Ọlọjọ to maa n waye lọdoọdun.
Nibẹ lo ti sọ pe ki awọn ọmọ Naijiria maa reti ayipada rere ni gbogbo ẹka eto ọrọ aje orilẹ-ede yii, nitori pe ko si bi awọn araalu ko ṣe nii ri ipa rere adura ti wọn ṣe nibi ọdun Ọlọjọ.
Bakan naa ni Ọọni tun sọ pe ina to ṣẹyọ lakooko toun gbe ade 'Aare' sori lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yi ti jẹ apẹẹrẹ ọjọ iwaju rere fun orilẹ-ede yii.
No comments:
Post a Comment