Adanu nla gbaa ni wọn sọ pe iku gendebinrin kan, Alice Liman jẹ fun gbogbo awọn mọlẹbi rẹ, paapaa ọkọ afẹsọna ti wọn ti jọ da ọjọ igbeyawo sọna.
Ogbọn ọjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii la gbọ pe Alice ati ọkọ afẹsọna rẹ, Kadama Birgamus fẹẹ ṣe igbeyawo alarinrin, koda, ti wọn ti file po ọti, ti gbogbo ipalẹmọ ayẹyẹ naa si fẹẹ pari.
AWIKONKO gbọ pe awọn mọlẹbi ti mu aṣọ, wọn si ti san owo gbọngan ibi ti ayẹyẹ igbeyawo naa ti fẹẹ waye.
Ero rẹpẹtẹ la gbọ pe wọn n palẹmọ fun ọjọ naa, ti onikaluku si ti n ṣeleri bi wọn ṣe maa dabira lọjọ naa.
Ijọba ibilẹ Yola South, nipinlẹ Adamawa la gbọ pe igbeyawo naa fẹẹ waye.
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi iku to pa Alice mulẹ lakooko taa pari akojọpọ iroyin yii, ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe ko ju bi wakati meloo kan to bẹrẹ aisan ni wọn lo gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Okan lara awọn to ti n palẹmọ fun ọjọ naa, Samuel Mombol, lo tun gbe iroyin ibanujẹ naa sori ikanni ayelujara nirọlẹ ana, Sunday, Aiku, to si ni adanu nla nilu rẹ jẹ fun wọn ati gbogbo ẹbi.
Pupọ awọn to gbọ si iṣẹlẹ kayeefi yii ni wọn n sọ pe iku Alice kii ṣoju lasan, ṣugbọn ti ko sẹni to le sọ pato bo ṣe jẹ.
No comments:
Post a Comment