Abùjá ni Ahmẹd ti n jí mọ́tò gbé, Zamfara lọwọ́ tí tẹ̀ ẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 6, 2021

Abùjá ni Ahmẹd ti n jí mọ́tò gbé, Zamfara lọwọ́ tí tẹ̀ ẹ́


Owọ ileeṣẹ ọlọpaa Federal Capital Territory (FCT) nilu Abuja ti tẹ baale ile ẹni ọdun medinlogoji kan ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju ko maa ji mọto gbe kaakiri igboro ilu Abuja, ko si lọ maa ta a danu lowo pọọku, Badawi Abdullahi Ahmed.


Agbegbe kan ti wọn pe ni Talata Mafara nipinlẹ Zamfara lọwọ palaba Ahmẹd ti segi pẹlu mọto Toyota Corolla ti nọmba idanimọ ẹ jẹ FKJ 625 DV to ji gbe gbẹyin.
 
AWIKONKO gbọ pe adugbo kan to n jẹ Aguiyi Ironsi, eyi to wa lagbegbe Maitama nilu Abuja ni wọn sọ pe Ahmẹd ti ji mọto naa gbe laipẹ yii, ti wọn si lọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
 
Daniel Ndirpaya to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abuja to firoyin ọhun to wa leti sọ pe ṣe lawọn tọpinpin Ahmẹd de ibi tọwọ ti tẹ ẹ.
 
O ni awọn gba mọto naa lọwọ ẹ, pẹlu kọkọrọ to le ṣi mọto pupọ ati baagi to kun fun irinṣẹ mọto, to si lawọn yoo foju rẹ ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.
 
Daniel tẹsiwaju pe ọga awọn, Babaji Sunday ti gbe awọn nọmba kan sita fawọn araalu lati pe, iyẹn bi wọn ba kofiri eeyan to n rin pẹlu ifura lagbegbe wọn. Awọn nọmba naa niwọnyi 08032003913, 08061581938, 07057337653 ati 08028940883.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI