Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu AbdulGaniyu Sani gẹgẹ bi akọwe eto iṣuna agba {Accountant General} nipinlẹ naa, bẹẹ tun bura fawọn kọmiṣanna tuntun meji ọtọọtọ.
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe ijọba ipinlẹ naa ti gbe ipolowo jade wi pe ki awọn to ba kun oju oṣuwọn lati di ipo naa mu fi ara wọn han, ti awọn mẹrin si jade lati farahan lotitọ.
Lẹyin ọpọlọpọ ayẹwọ ati idanrawo, la gbọ pe Sanni, ẹni to kawe gboye lẹka iṣiro ati agbẹjọro, jawe olubori laaarin awọn mẹrin to dide du ipo naa.
Ọmọ bibi ilu Ilọrin naa la gbọ pe o ti ṣiṣẹ lawọn oriṣiriṣi ẹka ileeṣẹ to nii ṣe pẹlu ọrọ iṣiro owo ati eto iṣuna.
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Institute of Chartered Accountants of Nigeria (ICAN); Nigeria Institute of Management; Association of National Accountant of Nigeria (ANAN); National Institute of Marketing; ati Institute of Management Consultants.
Lara awọn ile-ẹkọ to lọ ni Fasiti Abubakar Tafawa Balewa (MBA, Finance); Ile-ẹkọ gbogboniṣe tipinlẹ Kaduna (PGD Marketing Management); ati Ile-ẹkọ gbogboniṣe tipinlẹ Kwara (OND ati HND, Business Administration). Bẹẹ lo tun jẹ ọkan lara awọn alẹnulọrọ nile-ẹkọ girama tilu Ilọrin, iyẹn nibi to ti kẹkọọ jade lọpọlọpọ ọdun sẹyin.
No comments:
Post a Comment