Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́ lu ọsibitu igbalode ti wọn ti n tọju awọn to ba ni arun ọpọlọ si ipinlẹ Kwara, pẹlu erongba lati jẹ ki awọn alaaganna dinku lawujọ.
Ọsibitu naa la gbọ pe yoo jẹ olori awọn ọsibitu iru ẹ to wa kaakiri aarin gbungbun ila oorun (North Central) orilẹ-ede Naijiria..
Ninu atẹjade ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye lọjọ Aiku, Sannde lo ti fi imọriri re han si Aarẹ Buhari.
AbdulRazaq sọ pe ala rere awọn ọjọ pipẹ lo wa si imuṣẹ fun ijọba ati awọn Sẹnetọ mẹta ti wọn wa lati Kwara, paapaa Sẹnetọ Yahya Oloriẹgbẹ, ẹni to ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe iṣẹ naa di ṣíṣe.
No comments:
Post a Comment