'Ọmọ Yahoo' mẹ́ẹ̀dógún dèro ọgbà ẹ̀wọ̀n l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 25, 2021

'Ọmọ Yahoo' mẹ́ẹ̀dógún dèro ọgbà ẹ̀wọ̀n l'Abuja


Ko din ni awọn afurasi ọmọ 'Yahoo Yahoo' mẹẹdogun ti wọn ti wa lahamọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Abuja.
 
Benjamin Obiakor, Emmanuel Simon, Ibrahim Oyelade, Taiwo Samuel, Oko Emmanuel Chinedu, Uchechukwu Edozie ati Obi Emeka Reginald lorukọ wọn.
 
Awọn yooku ni Jerry Gabriel, Athnetus Ezeh, Michael Aaron, Ebube Gabriel, Ikechukwu Collins, Izoduwa Osemwegie, Augustine Kelvin, Morrison Marvin, Stanley Okereke, Victor Ajah, Ibrahim Ojonugwa, Chijioke Nnaka, Chikezie Wisdom ati Chijioke Ifendu.
 
Gẹgẹ bi Wilson Uwujaren to jẹ alukoro ileeṣẹ naa ṣe fi to wa leti, o ni awọn agbegbe bi i Brick City ati Kagini to wa ni Kubwa nilu Abuja, Federal Capital Territory lọwọ ti tẹ gbogbo wọn lọsẹ to kọja, iyẹn Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ ti a wa yii.
 
Uwujaren sọ pe lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn nimọto bọginni meji ọtọọtọ, kọmputa alagbeeka marun-un ati foonu olowo nla mẹtala.
 
O wa jẹ ko ye wa pe gbogbo wọn ni yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI