Wọ́n ju baálé ilé sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirírikì nítorí ìbásùn tó n kó fáwọn ọmọ rẹ̀ l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 25, 2021

Wọ́n ju baálé ilé sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirírikì nítorí ìbásùn tó n kó fáwọn ọmọ rẹ̀ l'Ékòó


Ile-ẹjọ majisireeti to wa lagbegbe Ikẹja, nipinlẹ Eko lonii, Ọjọru, Wẹside ti ju baale ile ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan, Anthony Odita sọgba ẹwọn lori ẹsun wi pe o n ko ibasun fawọn ọmọ rẹ meji.

Onidajọ O.A Layinka lo gbe idajọ naa kalẹ wi pe kawọn ọlọpaa ṣi lọ fi Odita to n gbe ladugbo Igbogbo, agbegbe Ikorodu sọgba ẹwọn Kirikiri titi digba ti igbẹjọ yoo si pada waye.
 
A gbọ pe inu oṣu keje to kọja yii ni Odita ko ibasun fawọn ọmọ re ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹsan si mejila lọ.

Ẹsun naa la gbọ pe o tako ofin ọdaran ipinlẹ Eko, tọdun 2015, to si ni ijiya nla ninu.
 
Onidajọ Layinka wa sun igbẹjọ si ọjọ kẹfa, oṣu kejila, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI