Saraki gbe ijọba Kwara lọ sile-ẹjọ nitori owo ti wọn fẹẹ ya - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 20, 2021

Saraki gbe ijọba Kwara lọ sile-ẹjọ nitori owo ti wọn fẹẹ ya


Arẹ ile igbimọ aṣofin agba orilẹ-ede yii tẹlẹri, Sẹnetọ Bukọla Saraki ti gbe ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọ sile-ẹjọ lori owo ti wọn fẹẹ ya.
 
Saraki gbe Gomina AbdulRazaq lọ siwaju ile-ẹjọ giga  apapọ lati da a lọwọ kọ nipa yiya owo to to biliọnu marundinlogoji naira.
 
Ninu iwe ipẹjọ ti Saraki pe, eyi ti nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/848/2021 lo ti n bẹbẹ pe ki wọn ma ṣe gba Gomina AbdulRazaq laaye lati ya owo naa.
 
Lara awọn ti Saraki tun pe lẹjọ ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Onidajọ agba ipinlẹ naa, Ileeṣẹ eto iṣuna orilẹ-ede yii, Securities and Exchange Commission, Greenland & Growth SPV Limited, GTL Trustees Limited ati EAC Trustees.
 
Bẹ o ba gbagbe, Saraki lakooko to wa nipo gomina ipinlẹ naa lọdun 2009 ti gba biliọnu mẹtadinlogun naira lati fi ṣe awọn akanṣe iṣẹ.
 
Bakan naa ni gomina ana, Abdulfatah Ahmed lọdun 2014 gba owo yii,, biliọnu lọna ogun naira loun gba nigba lati fi tun opopona Michael Imoudu si Gamo ṣe, to si lo iyoku fun atunṣẹ awọn bi i opopona Kishi/Kaiama; papa iṣere Ilọrin atawọn mi in.
 
Lakooko ta a pari iroyin, a gbọ pe ile-ẹjọ ti fun awọn tọrọ kan niwe ipẹjọ lati yọju, ki wọn le wa a sọ tẹnu wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI