Afaimọ ni ko ma jẹ pe ọgba ẹwọn ni baale ile ọlọmọ mẹfa kan, Sunday Julius yoo ti lo eyi to ku nigbesi aye rẹ, lori bo ṣe n ko ibasun fawọn ọmọ rẹ obinrin mẹrin.
Awọn ọmọ naa la gbọ pe ọjọ ori wọn ko ti i ju ọdun mẹwaa si mẹẹdogun lọ la gbọ pe Sunday n ko ibasun fun karakara lagbegbe Mọṣalaṣi, nipinlẹ Eko.
Wọn ni Sunday lo ja ibale awọn ọmọ naa funra rẹ, lasiko ti iyawo rẹ, to jẹ iya awọn ọmọ naa ko ba si nile.
AWIKONKO gbọ pe aṣiri Sunday ti tu ni nnkan bi ọdun meje sẹyin, ti iyawo rẹ, Sẹmiat si lọ fi ọlọpaa gbe e, ṣugbọn ti wọn lawọn ara adugbo ni wọn ba a bẹbẹ, ko to di pe awọn ọlọpaa fi silẹ, to si ṣeleri wi pe oun ko tun ni ṣe bẹẹ mọ.
Sugbọn laipẹ yii ti ọwọ tun pada tẹ Sunday, ṣe lo fi ika abamọ sẹnu, to si n sunkun bi ọmọ ikooko ti wọn ṣẹṣẹ dako fun.
Odun 2007 la gbọ pe Sunday fẹ Sẹmiat gẹgẹ bi iyawo, ti wọn si bimọ mẹfa funra wọn, eyi ti mẹrin ninu awọn ọmọ naa jẹ obinrin. Akọbi rẹ to jẹ obinrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun la gbọ pe Sunday kọkọ n ko ibasun fun, ti aṣiri si tu.
Wọn ni gbogbo asiko ti Sẹmiat ko ba si nile, to ba ti lọ sibi iṣẹ oojọ to yan laayo ni Sunday maa n lo anfaani ẹ lati ko ibasun fawọn ọmọ rẹ yii, koda, ti wọn sọ pe yoo tun dide laaarn oru lati ba awọn ọmọ naa laṣepọ, ti iyawo rẹ ko si ni i taji.
Yara kan ṣoṣo la gbọ pe Sunday n gbe pẹlu iyawo ẹ ati awọn ọmọ mẹfẹẹfa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejọbi fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, to ni Sunday ti wa lahamọ wọn, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.
Adejọbi sọ pe ile-ẹjọ nikan lo le sọ iye ọdun ti Sunday yoo lo lẹwọn, nitori to sọ pe ọga awọn Hakeem Odumosu ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ lọ ni kikun.
No comments:
Post a Comment