Ọjọ Aje, Mọnde ijẹta tun jẹ ọjọ manigbagbe fun gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Alexander Abiodun Soyinka, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ayinla Ẹgba, lori bi wọn fi jẹ oye tuntun.
Titi dasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii lawọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ Ayinla Ẹgba ṣi fi n ki ku oriire ti oye tuntun naa, tawọn kan si n sọ pe o gbọdọ wuye naa.
Ayinla Ẹgba ti awọn eeyan tun n pe ni Baba Oni Matina la gbọ pe awọn agbaagba ilu Ijẹmọ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun fi jẹ oye Amuludun ilu Ijẹmọ.
AWIKONKO gbọ pe lara awọn ipa ti ọkunrin naa ti ko lawujo nilu Ijẹmọ, paapaa bo tun ṣe n fi iṣẹ sọrọsọrọ to yan laayo gbe ilu naa larugẹ, gẹgẹ bi ibi to ti wa lo jẹ ki wọn fi oye naa ta a lọrẹ.
Lara awọn to wa nibi ti wọn ti fun Ayinla ni oye tuntun naa ni alaga ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Olufẹmi Iyanda Omilani, atawọn mi-in.
No comments:
Post a Comment