Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mo wà tí bàbá ti ń bá mi láṣepọ̀ - Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ̀rọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 27, 2021

Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mo wà tí bàbá ti ń bá mi láṣepọ̀ - Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ̀rọ̀


Omọ ọdun mẹtadinlogun kan lo ti jẹwọ fawọn ọlọpaa bayii wi pe ọmọ ọdun mẹwaa loun wa nigba baba oun, ẹni ọdun marundinlaadọta [45] ti n ba oun laṣepọ, to si tun maa n dunkooko lati pa oun danu, boun ba tu aṣiri naa sita.
 
Ijọba ibilẹ Ondo West, nilu Ondo, ipinlẹ Ondo niṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
 
Omọ naa ta a forukọ bo laṣiri lo sọrọ yii sita fawọn ọlọpaa wi pe latigba ti mama oun ti kẹru jade nile baba oun, Nelson Akinṣọwọn lo ti sọ oun di iyawo rẹ ninu ile, to si n fojoojumọ ko ibasun foun karakara.
 
A gbọ pe ọdun 2014 ni Nelson ti n ba ọmọ rẹ yii laṣepọ ni gbogbo igba to ba ti loyun, lai jẹ kẹnikẹni mọ, ti wọn si ni oun yoo pa a danu, to ba fi le sọ fẹnikẹni.
 
Nigba ti wọn lọmọ yii ri i pe ara oun ko gba ibalopọ ojoojumọ naa mọ, lo mu sa jade, to si lọ sọ fawọn to ran an lọwọ.
 
Olukọ ile-ẹkọ girama ni wọn pe Nelson, ti wọn si ni aibikita rẹ lo jẹ ki iyawo rẹ, to jẹ iya ọmọ to n ba lopọ yii lo jẹ ko kẹru jade lati lọ wa ibi ti yoo ti tọju ara rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI