Ohun tí mo fẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run - Gbajúmọ̀ pèdèpèdè, Skeledy Ọmọ Perry sọ̀rọ̀ nípa ayẹyẹ ọjọ ìbí rẹ̀ lónìí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 24, 2021

Ohun tí mo fẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run - Gbajúmọ̀ pèdèpèdè, Skeledy Ọmọ Perry sọ̀rọ̀ nípa ayẹyẹ ọjọ ìbí rẹ̀ lónìí


Oni ni, ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu ayẹyẹ ọjọ ibi gbajugba pedepede nni, Salami Adedeji, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Skeledy Ọmọ Perry.

Lati idaji oni lawọn ololufẹ ọkunrin naa ti n fi atẹjiṣẹ ikini ranṣẹ si i, lati ba a yọ anfaani nla to tun ri gba lọwọ Ọlọrun.

Koda, titi di asiko ta a pari akojọpọ iroyin yii lawọn ẹlẹgbẹ lori redio, tẹlifiṣan ati ikanni ayelujara loriṣiriṣi ṣi n ki ku oriire naa.

Nigba toun funra rẹ n fi ẹmi imoore rẹ han s'Ọlọrun, Skeledy sọ pe:

"Ọlọrun ni mo fi ọpẹ fun bi ọjọ ibi mi tun ṣe ko layọ lonii. Ki i ṣe pe mo mọ rara, ṣugbọn awọn obi mi fi ye mi pe ayajọ oni, ninu oṣu kẹjọ yii ni wọn bi mi sile aye.

"Ohun ti mo n fi ọjọ ibi mi oni beere lọwọ Ọlọrun ni Ogo didan tuntun bi mo ti bẹrẹ tuntun lonii"






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI