Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti sọ pe Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo ku fun oun ni baba bayii, latigba ti baba oun ti jade laye.
Ana, ọjọ Aiku, Sannde ni Gomina Abiọdun sọrọ yii jade, nigba i Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ṣabẹwo si i, lati ba a kẹdun iku baba rẹ, Pa Emmanuel Abiọdun to doloogbe laipẹ yii.
Ile Gomina to wa niluu Ipẹru-Rẹmọ, ipinlẹ Ogun ni Ẹbọra Owu ti lọ ba Gomina Abiọdun kẹdun, nibẹ lo si ti sọ pe ẹnikan ṣoṣo toun tun n wo loju gẹgẹ bi baba bayii ni Ọbasanjọ.
Nigba to n sọrọ, Ọbasanjọ sọ pe lara awọn ẹkọ toun ri kọ ninu iku Alagba Emmanuel Abiọdun ni pe gbogbo eeyan lo maa fi aye silẹ lọjọ kan, ati pe bi asiko onikaluku ba ṣe n to, ni wọn yoo ṣe maa dagbere faye.
O ni ohun tawọn eeyan ba n sọ lẹyin teeyan ba ku tan ni yoo ṣe pataki, to si ni baba naa fi apẹẹrẹ rere lelẹ ko to jade laye, paapaa nigba to wa lẹnu iṣẹ gẹgẹ bi agba olukọni.
No comments:
Post a Comment