O ṣẹlẹ! Omọ ọdun marundinlọgbọn dana sun ara rẹ, nitori ọkọ rẹ fẹẹ fẹyawo keji lee - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 9, 2021

O ṣẹlẹ! Omọ ọdun marundinlọgbọn dana sun ara rẹ, nitori ọkọ rẹ fẹẹ fẹyawo keji lee


Iyalẹnu nla gbaa lọrọ iyale ile ẹni ọdun marundinlọgbọn kan, Maimuna Wadaji ti wọn loo dana sun ara rẹ nitori ọkọ rẹ pinnu lati fẹ iyawo keji le.
 
Abule kan ti wọn pe ni Rungumau, to wa nijọba ibilẹ Dutse, ipinlẹ Jigawa niṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Aiku, Sannde ana.
 
Gẹgẹ bi wọn ṣe fi iṣẹlẹ ọhun to AWIKONKO lọwọ,wọn loo ti pẹ ti ọkọ Maimuna ti n sọ fun un pe oun ko ni pẹ ẹ fẹ obinrin mi in le, ti wọn yoo si di meji.

A gbọ pe Maimuna ti gbe oriṣiriṣi igbesẹ lati ma jẹ ki ọkọ rẹ fẹ obinrin mi in, gẹgẹ bi ipinnu rẹ, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko si nnkan to le ma jẹ koun fẹ iyawo keji.
 
Wọn ni ṣe ni ọkunrin naa duro lori ipinnu rẹ wi pe oun yoo fẹ iyawo keji, ati pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari.
 
Nigba ti wọn sọ pe Maumuna ri i pe ọkọ rẹ ko fẹẹ yi ipinnu naa pada, loun naa ba gba ile-epo lọ, lati lọp ra bẹntiroolu.
 
Bo ṣe gbe bẹntiroolu naa dele, lo da a si ara rẹ lori, to si ṣa iṣana si i.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI