Mọlẹbi Abiọdun ti kede sita wi pe ọjọ mẹrin gbako lawọn yoo ṣeto isinku baba wọn, Ọmọwe Emmanuel Adesanya Abiọdun to doloogbe laipẹ yii.
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lo sọrọ yii jade loni, ọjọ Aje, Mọnde wi pe awọn ti mu awọn ọjọ tawọn yoo sinku naa, ati pe ọjọ kẹfa si ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹsan-an ni yoo waye.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjkọ kẹfa si Ọjọbọ, Tọsidee, oṣu kẹsan to n bọ ni eto isinku ọhun yoo waye niluu Ipẹru-Rẹmọ, ipinlẹ Ogun.
Nigba to n gba ẹnu akọwe rẹ, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin sọrọ, Gomina Abiọdun to jẹ akọbi ninu awọn ọmọ oloogbe naa dupẹ gidigidi lọwọ gbogbo awọn abanikẹdun, to si loun ko le gbagbe wọn titi lai.
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ wi pe Gomina Abiọdun yoo maa wa nile lati gbalejo awọn to ba fẹ wa ba a kẹdun iku baba rẹ ni gbogbo opin ọsẹ.
No comments:
Post a Comment