David Akpokpokpo ti sọ pe loootọ loun ba ọmọ oun laṣepọ, ti ọmọ naa si loyun foun, koda, to tun fi oyun naa bi ọmọ foun ni nnkan bi oṣu mẹta sẹyin.
Baale ile yii, iyẹn David lo tu aṣiri yii ninu fọnran kan to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii, nibi to ti n ka boroboro.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Amukpe nilu Sapẹlẹ, ipinlẹ Delta la gbọ pe David n gbe pẹlu ọmọ rẹ, Mercy to fun loyun.
Bo tilẹ jẹ pe David sọ pe ẹẹkan ṣoṣo pere loun ba Mercy, ọmọ oun laṣepọ ko to doyun, to si ni iṣẹ eṣu ni, ati pe ọti toun mu lọjọ naa lo gbodi lara oun, ṣugbọn ti ọmọ naa sọ pe irọ ni, nitori pe ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni baba oun ko ibasun foun.
Kii ṣe pe aṣiri naa deede tu sita, ṣugbọn nitori pe ara Mercy ko gba a mọ lati jẹwọ fawọn eeyan to n fẹ mọ ẹni to bimọ naa fun, lo jẹ ko pariwo sita.
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe David ti dunkoko mọ ọmọ naa wi pe ko gbọdọ sọ ẹni to bimọ fun fẹnikẹni, bi ko ba fẹ ku lojiji, eyi to jẹ ki wọn ṣee loku oru, ṣugbọn to di pe ara ọmọ naa ko gbe e mọ, lo jẹ ko gba ọdọ awọn fijilante lọ, lati ṣalaye fun wọn.
No comments:
Post a Comment