Lẹ́yìn tó kúrò làhámọ́ EFCC, Saraki ju bọmbu ọ̀rọ̀ síta, ó ní... - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 1, 2021

Lẹ́yìn tó kúrò làhámọ́ EFCC, Saraki ju bọmbu ọ̀rọ̀ síta, ó ní...


Ana, ọjọ Abamẹta, Satide ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ranṣẹ pe Aarẹ ile igbimọ aṣofin lorilẹ-ede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki, nibi ti wọn ti fọrọ wa a lẹnu wo lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.

Fun bi ọpọlọpọ wakati la gbọ pe Saraki lo lọdọ awọn EFCC ko to di pe wọn fi silẹ ni nnkan bi irọlẹ mọ alẹ.
 
Lẹyin eyi ni agbẹnusọ rẹ, Yusuph Ọlaniyọnu gbe atẹjade sita lori awuyewuye to ti kaakiri nipa idi ti EFCC ṣe ranṣẹ pe Saraki.
 
Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe oun ko lẹbọ-lẹru lori awọn dukia toun ko jọ. O ni ki i ṣe pe awọn EFCC wa a gbe Saraki, tabi fọwọ ofin gbe Saraki, bi ko ṣe pe funra rẹ lo lọ jẹ wọn, nitori pe ko si nnkan to fẹẹ fi pamọ. 
 
O ni ki i ṣe pe wọn pe Saraki lori pe o gbe owo rin lọna ti ko tọ, iyẹn ti awọn oloyinbo n pe ni 'money laundering'.
 
AWIKONKO gbọ pe Sẹnetọ Buraki ti lo oriṣiriṣi ileeṣẹ fi gba akanṣe iṣẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso rẹ, ti wọn si n san owo pada fun un lọdọọdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI