Lẹ́yìn tí Baálẹ̀ Onidundun dèrò ẹ̀wọ̀n, ọwọ́ tẹ àwọn méjì tó pa olórí ọ̀dọ̀ danù n'Íbàdàn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 3, 2021

Lẹ́yìn tí Baálẹ̀ Onidundun dèrò ẹ̀wọ̀n, ọwọ́ tẹ àwọn méjì tó pa olórí ọ̀dọ̀ danù n'Íbàdàn


Ko din ni meji tọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ lori iku olori ọdọ abule Onidundun to wa nijọba ibilẹ Akiyẹle niluu Ibadan, ipinlẹ naa, iyẹn Usman Mohammed.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa lo foju awọn afurasi ọdaran naa han fawọn akọroyin laipẹ yii, bẹẹ ni wọn tun foju awọn mọkanlelọgbọn mi in han lori iwa ọdaran loriṣiriṣi bi i ijinigbe, paniyan, jibiti ati bẹẹbẹẹlọ.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ngozi Ọnadẹkọ ninu ọrọ rẹ sọ pe ọjọ kẹsan an, oṣu to kọja yii ni ẹnikan to n jẹ Umaru Mohammed pe Taofeek Ọlaide lori foonu wi pe oun ni maalu kan toun fẹẹ ta.
 
Wọn ni Umaru sọ fun Taofeek pe baba oun to n ta ẹran ni lọja Kara to wa lagbegbe Akinyẹle lo sọ pe koun lọ maluu naa.
 
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe Ọlaide ti pe ọrẹ rẹ kan, Yusuf Taiwo lati jọ lọ wo maluu naa, ti wọn si gbe ọkada lọ sibẹ. Oju ọna la gbọ pe wọn ti pada gbe Umaru, ko le mu wọn debi ti maalu ọhun wa, ki wọn le duna dura lai mọ pe Umaru ti dẹ awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ ajinigbe sibẹ.
 
Bi wọn ṣe n debẹ la gbọ pe awọn ajinigbe to n duro de wọn ti dabọn bolẹ fun wọn, ti wọn si ni Taofeek raaye salọ, ṣugbọn ti ọwọ wọn pada tẹ Yusuf.
 
Taofeek lo lọ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ naa fawọn ọlọpaa, to fi di pe wọn sare lọ sibẹ. Awọn ọlọpaa ẹkun Mọniya atawọn ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe la gbọ pe wọn jọ lọ, pẹlu awọn fijilante.
 
Nibẹ ni wọn ti ri Yusuf gba silẹ lẹyin ọpọlọpọ ifarapa. 
 
A gbọ pe nibi ti wọn ti n salọ, ki ọwọ ọlọpaa ma ba a tẹ wọn ni wọn ti ja si abule Onidundun, ti wọn si yinbọn saarin awọn ọdọ to duro n sọrọ lọwọ.
 
Ninu ọta ibọn ti wọn yin la gbọ pe o ti ba olori ọdọ abule naa, to si ku loju ẹsẹ. Gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi, paapaa nigba ti wọn tun gbe e lọ si ọsibitu lo ja si pabo.
 
Ọnadẹkọ wa a fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan naa yoo foju ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to ba tọ si wọn, iyẹn lẹyin iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI