Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti sọ pe ko sẹni to wọgile ipade gbogboogbo abẹle to waye ninu ẹgbẹ naa kaakiri orilẹ-ede yii, nitori naa, wọn ni kẹnikẹni ma ṣe gba iroyin naa gbọ rara, nitori pe ko si otitọ kankan nibẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe igbimọ ẹgbẹ naa to n ri si bi ipade gbogboogbo ọhun yoo ṣe waye lapapọ, iyẹn Caretaker/Extraordinary Convention Planning Committee (CECPC), Sẹnetọ John James Akpanudoedehe gbe jade laipẹ yii lo ti sọ pe eto naa lọ bo ti tọ, ati bo ti yẹ.
O ni awọn ko wọgile eto naa, bẹẹ naa lawọn ko gbe e ti sẹgbẹ kan, nipa wi pe wọn yoo tun un ṣe.
No comments:
Post a Comment